• adedayo_omooba 16w

  ÌGBÀ

  Ìgbà ò lọ bí òréré
  Ojọ́ ńgorí ọjọ
  Ìgbà ńgorí Ìgbà
  Ewé tútù Òní ńbọ̀ wá dì ìràwé bód'ọ̀la
  Kí Ọba òkè fún wa ní ọgbọ́n aṣíraṣe
  Kí Elédùà ó fún wa ní ìmọ̀ ataraṣàṣà
  Torí ọjọ ń lọ béèsìni àkókò ó dúrò dé ẹnìkán-àn-kan

  ©adedayo_omooba